Jeremiah 27:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ikọ̀ kan wá sí ọ̀dọ̀ Sedekaya, ọba Juda, ní Jerusalẹmu, láti ọ̀dọ̀ ọba Edomu ati ọba Moabu, ọba àwọn ọmọ Amoni, ọba Tire, ati ọba Sidoni wá, rán wọn pada sí àwọn oluwa wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o rán wọn lọ si ọdọ ọba Edomu, ati si ọba Moabu, ati si ọba awọn ọmọ Ammoni, ati si ọba Tire, ati si ọba Sidoni, lọwọ awọn ikọ̀ ti o wá si Jerusalemu sọdọ Sedekiah, ọba Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o rán ọ̀rọ̀ sí Ọba ti Édómù, Móábù, Ámónì, Tírè àti Sídónì láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jérúsálẹ́mù sọ́dọ̀ Sedekáyà Ọba Júdà.