Jeremiah 27:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóo máa ṣe ẹrú òun ati ọmọ rẹ̀, ati ọmọ ọmọ rẹ̀, títí àkókò tí ilẹ̀ òun pàápàá yóo fi tó, tí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba ńláńlá yóo sì kó o lẹ́rú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati orilẹ-ède gbogbo ni yio sin on, ati ọmọ rẹ̀ ati ọmọ-ọmọ rẹ̀, titi di ìgba ti akoko ilẹ tirẹ̀ yio de; lara rẹ̀ ni orilẹ-ède pupọ ati awọn ọba nla yio jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo orílẹ̀ èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè àti àwọn Ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.