Jeremiah 27:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè tabi ìjọba kan bá kọ̀, tí wọn kò sin Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí wọn kò sì ti ọrùn wọn bọ àjàgà rẹ̀, ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ni n óo fi jẹ orílẹ̀-èdè náà níyà títí n óo fi fà á lé ọba Babiloni lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, orilẹ-ède ati ijọba ti kì yio sin Nebukadnessari ọba Babeli, ti kì yio fi ọrùn wọn si abẹ àjaga ọba Babeli, orilẹ-ède na li emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, jẹ niya, li Oluwa wi, titi emi o fi run wọn nipa ọwọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘ “Àmọ́ tí orílẹ̀ èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadinésárì Ọba Bábílónì, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀; Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ni OLÚWA wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.