Jeremiah 27:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín, ati àwọn awoṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín ati àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, ati àwọn oṣó yín, tí wọn ń sọ fun yín pé ẹ kò ní di ẹrú ọba Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ máṣe fi eti si awọn woli nyin, tabi si awọn alafọṣẹ nyin, tabi si awọn alála, tabi si awọn oṣo nyin, tabi awọn ajẹ nyin ti nsọ fun nyin pe, Ẹnyin kì o sin ọba Babeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tabi àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Èyin kò ní sin Ọba Bábílónì.’