Jeremiah 28:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kan náà, ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda, ní oṣù karun-un ọdún kẹrin, Hananaya wolii ọmọ Aṣuri, tí ó wá láti Gibeoni bá mi sọ̀rọ̀ ní ilé OLUWA lójú àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan pé,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li ọdun kanna li atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, li ọdun kẹrin ati oṣù karun, ti Hananiah, ọmọ Asuri woli, ti iṣe ti Gibeoni, wi fun mi ni ile Oluwa, niwaju awọn alufa ati gbogbo enia pe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní oṣù karùn ún ní ọdún kan náà, ọdún kẹrin ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba Sedekáyà Ọba Júdà, wòlíì Hananáyà ọmọ Ásúrì, tí ó wá láti Gíbíónì, sọ fún mi ní ilé OLÚWA tí ó wà ní iwájú àwọn àlùfáà àti gbogbo ènìyàn: