Jeremiah 28:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hananaya bá sọ níṣojú gbogbo eniyan pé OLUWA ní bẹ́ẹ̀ ni òun óo ṣẹ́ àjàgà Nebukadinesari ọba Babiloni kúrò lọ́rùn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè kí ọdún meji tó pé. Wolii Jeremaya bá bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hananiah si wi niwaju gbogbo enia pe, Bayi li Oluwa wi; Bẹ̃ gẹgẹ li emi o ṣẹ́ ajaga Nebukadnessari, ọba Babeli, kuro li ọrùn orilẹ-ède gbogbo ni igba ọdun meji. Jeremiah woli si ba ọ̀na tirẹ̀ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ‘Bákan náà ni mà á fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì láàrin ọdún méjì.’ ” Jeremáyà sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.