Jeremiah 28:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun ti fi àjàgà irin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè wọnyi kí wọn lè di ẹrú Nebukadinesari ọba Babiloni, kí wọn sì máa sìn ín, nítorí òun ti fi àwọn ẹranko inú igbó pàápàá fún un.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi: emi ti fi ajaga irin si ọrùn gbogbo orilẹ-ède wọnyi, ki nwọn ki o sin Nebukadnessari, ọba Babeli, nwọn o si sin i, emi si fi ẹranko igbẹ fun u pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: mà á fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀ èdè láti lè máa sin Nebukadinésárì ti Bábílónì, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Mà á tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”