Jeremiah 28:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òun óo mú Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu, ati gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú láti Juda lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí, nítorí òun óo ṣẹ́ àjàgà ọba Babiloni. Ó ní OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si tun mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pẹlu awọn igbekun Juda, ti o ti lọ si Babeli pada wá si ibi yi, li Oluwa wi, nitori emi o si ṣẹ àjaga ọba Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi á tún mú àyè Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Júdà ní Bábílónì,’ èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ Ọba Bábílónì yóò rọrùn.’ ”