Jeremiah 28:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó ní, “Amin, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀. Kí OLUWA mú àsọtẹ́lẹ̀ tí o sọ ṣẹ, kí ó kó àwọn ohun èlò ilé rẹ̀ ati gbogbo àwọn eniyan tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni pada sí ibí yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jeremiah woli si wipe, Amin: ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃: ki Oluwa ki o mu ọ̀rọ rẹ ti iwọ sọ asọtẹlẹ ṣẹ, lati mu ohun-elo ile Oluwa ati gbogbo igbekun pada, lati Babeli wá si ibi yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sọ wí pé, “Àmín! Kí OLÚWA ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí OLÚWA ó mú àwíṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun èlò ilé OLÚWA àti gbogbo àwọn aṣàtìpó padà sí ilẹ̀ Bábílónì.