Jeremiah 29:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jeremaya wolii kọ ìwé kan ranṣẹ láti Jerusalẹmu, ó kọ ọ́ sí àwọn àgbààgbà láàrin àwọn tí a kó ní ìgbèkùn; ati sí àwọn alufaa ati àwọn wolii, ati gbogbo àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, láti Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
WỌNYI si li ọ̀rọ iwe ti Jeremiah woli rán lati Jerusalemu si iyokù ninu awọn àgba ti o wà ni igbèkun, ati si awọn alufa, ati awọn woli, ati si gbogbo enia ti Nebukadnessari kó ni igbekun lọ lati Jerusalemu si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremáyà fi ránṣẹ́ láti Jérúsálẹ́mù sí àwọn tí ó yè nínú àwọn aṣàtìpó àti àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn Nebukadinésárì tí wọ́n ṣe àtìpó láti Jérúsálẹ́mù ní Bábílónì.