Jeremiah 29:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà tí aadọrin ọdún Babiloni bá pé, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ yín, n óo mú ìlérí mi ṣẹ fun yín, n óo sì ko yín pada sí ibí yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti ãdọrin ọdun ba pari ni Babeli, li emi o bẹ̀ nyin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Bábílónì, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jérúsálẹ́mù.