Jeremiah 29:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o di ríri fun nyin, li Oluwa wi: emi o si yi igbekun nyin pada kuro, emi o si kó nyin jọ lati gbogbo orilẹ-ède ati lati ibi gbogbo wá, nibiti emi ti lé nyin lọ, li Oluwa wi; emi o si tun mu nyin wá si ibi ti mo ti mu ki a kó nyin ni igbekun lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì mú yín kúrò ní ìgbékùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀ èdè àti ibi gbogbo tí mo ti lé yín jáde. Èmi yóò sì kó yín padà sí Jérúsálẹ́mù ibi tí mo ti kó jáde lọ sí ilé àtìpó.”