Jeremiah 29:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Wò o, emi o rán idà sarin wọn, ìyan, ati àjakalẹ-àrun, emi o ṣe wọn bi eso-ọ̀pọtọ buburu, ti a kò le jẹ, nitori nwọn buru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí pé: “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn sí wọn; Èmi yóò sọ wọ́n dà bí ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ.