Jeremiah 29:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, ‘N óo fi ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn bá wọn jà, òun óo sì sọ wọ́n di àríbẹ̀rù fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Wọn yóo di ẹni ègún, àríbẹ̀rù, àrípòṣé ati ẹni ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé wọn lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si fi idà, ìyan, ati àjakalẹ-arun lepa wọn; emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, fun egún, ati iyanu, ati ẹsin, ati ẹ̀gan, lãrin gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi o le wọn si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn ni Èmi yóò fi lé wọn; Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, àti ohun ẹ̀gún àti ẹ̀rù; ohun ẹ̀gbin àti ohun ẹ̀dùn láàrin gbogbo orílẹ̀ èdè ayé.