Jeremiah 29:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ tí mo rán àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, láti sọ fún wọn nígbà gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti nwọn kò gbọ́ ọ̀rọ mi, li Oluwa wi, ti emi rán si wọn nipa awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, emi dide ni kutukutu mo si rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò fẹ igbọ́, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí wọ́n kọ̀ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,” ni OLÚWA Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ni ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni OLÚWA Ọlọ́run wí.