Jeremiah 29:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Jehoiakini, ati Sedekaya ọmọ Maaseaya, tí wọn ń forúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fun yín ni pé: òun óo fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì pa wọ́n lójú yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi, niti Ahabu ọmọ Kolaiah, ati niti Sedekiah ọmọ Maaseiah, ti nsọtẹlẹ eke fun nyin li orukọ mi; wò o, emi fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli; on o si pa wọn li oju nyin;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run sọ nípa Áhábù ọmọ Kóláháyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Máséà tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an.