Jeremiah 29:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí ìwé tí o fi orúkọ ara rẹ kọ sí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu, ati sí Sefanaya alufaa, ọmọ Maaseaya, ati sí gbogbo àwọn alufaa, pé:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitoripe iwọ ti rán iwe li orukọ rẹ si gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu ati si Sefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, ati si gbogbo awọn alufa, wipe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù sí Sefanáyà ọmọ Mááséà tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefanáyà wí pé,