Jeremiah 29:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ranṣẹ sí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn wí pé ohun tí OLUWA wí nípa Ṣemaaya ará Nehelamu ni pé: nítorí pé Ṣemaaya sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí òun kò rán an, ó sì mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ èké,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ranṣẹ si gbogbo awọn igbekun, wipe, Bayi li Oluwa wi niti Ṣemaiah, ara Nehalami, nitoripe Ṣemaiah ti sọtẹlẹ fun nyin, ṣugbọn emi kò ran a, ti on si mu nyin gbẹkẹle eke:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn àtìpó: ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ nípa Ṣemáyà àti Neelamaiti: Nítorí pé Semaíà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un yín, súgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké.