Jeremiah 29:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
òun OLUWA óo fìyà jẹ Ṣemaaya ará Nehelamu náà ati ìran rẹ̀; kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóo wà láàyè láàrin àwọn eniyan rẹ̀ láti fojú rí nǹkan rere tí n óo ṣe fún àwọn eniyan mi, nítorí ó ti sọ̀rọ̀ ọ̀tẹ̀ sí OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, bayi li Oluwa wi: Wò o, emi o bẹ Ṣemaiah, ara Nehalami, wò, ati iru-ọmọ rẹ̀; on kì yio ni ọkunrin kan lati ma gbe ãrin enia yi; bẹ̃ni kì yio ri rere na ti emi o ṣe fun awọn enia mi, li Oluwa wi; nitoripe o ti ṣọ̀tẹ si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé, Èmi kò rán Ṣemáyà ní àṣọtẹ́lẹ̀ tí ó sọ fún un yín, ó sì ti mú kí ẹ gba àṣọtẹ́lẹ̀ èké gbọ́. Èmi yóò fi ìyà jẹ Ṣemáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀. Kò sí ẹni tí yóò ṣẹ́kù nínú àwọn ìran rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí àwọn ohun rere tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi, nítorí ó ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi, ni OLÚWA wí.’ ”