Jeremiah 29:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹ si mã wá alafia ilu na, nibiti emi ti mu ki a kó nyin lọ ni igbekun, ẹ si mã gbadura si Oluwa fun u: nitori ninu alafia rẹ̀ li ẹnyin o ni alafia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ire ilẹ̀, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí OLÚWA fún ire ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.”