Jeremiah 3:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ṣé bí ọkọ bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí iyawo náà sì kó jáde nílé ọkọ, tí ó lọ fẹ́ ẹlòmíràn, ṣé ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ lè tún lọ gbà á pada? Ṣé ilẹ̀ náà kò ní di ìbàjẹ́? Lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe àgbèrè pẹlu ọpọlọpọ olólùfẹ́; ẹ wá fẹ́ pada sọ́dọ̀ mi?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SA wò o, bi a wipe ọkunrin kan kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, ti aya na si kuro lọdọ rẹ̀, ti o si di aya ẹlomiran, ọkunrin na le tun tọ̀ ọ wá? ilẹ na kì yio di ibajẹ gidigidi? ṣugbọn iwọ ti ba ayanfẹ pupọ ṣe panṣaga, iwọ o tun tọ̀ mi wá! li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn, ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá? Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí? Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́, ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?” ni OLÚWA wí.