Jeremiah 3:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé: ‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí. N kò ní máa bínú lọ títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọ ki o si kede ọ̀rọ wọnyi ni iha ariwa, ki o si wipe, Yipada iwọ Israeli, apẹhinda, li Oluwa wi, emi kì yio jẹ ki oju mi ki o korò si ọ; nitori emi ni ãnu, li Oluwa wi, emi kì o si pa ibinu mi mọ titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá: “ ‘Yípadà, Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́,’ ni OLÚWA wí. ‘Ojú mi kì yóò le sí yín mọ́, nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni OLÚWA wí.