Jeremiah 3:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi, ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa, lábẹ́ gbogbo igi tútù; o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa jẹwọ ẹ̀ṣẹ rẹ pe, iwọ ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe, o si tú ọ̀na rẹ ka fun awọn alejo labẹ igi tutu gbogbo, ṣugbọn ẹnyin kò gba ohùn mi gbọ́, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, o ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ, o ti wá ojú rere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi, tí ó tẹ́wọ́, o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,’ ” ni OLÚWA wí.