Jeremiah 3:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pada, ẹnyin apẹhinda ọmọ, li Oluwa wi, nitori emi gbe nyin ni iyawo; emi o si mu nyin, ọkan ninu ilu kan, ati meji ninu idile kan; emi o si mu nyin wá si Sioni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni OLÚWA wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Síónì.