Jeremiah 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe nigbati ẹnyin ba pọ̀ si i, ti ẹ si dàgba ni ilẹ na, li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi; nwọn kì yio si tun le wipe, Apoti-ẹri majẹmu Oluwa; bẹ̃ni kì yio wọ inu wọn, nwọn kì yio si ranti rẹ̀, nwọn kì yio tọ̀ ọ wá pẹlu, bẹ̃ni a kì yio si tun ṣe e mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni OLÚWA wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí OLÚWA’ kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́.