Jeremiah 3:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn o pè Jerusalemu ni itẹ Oluwa; gbogbo orilẹ-ède yio kọja tọ̀ ọ wá si orukọ Oluwa, si Jerusalemu, bẹ̃ni nwọn kì yio rìn mọ nipa agidi ọkàn buburu wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jérúsálẹ́mù ní ìtẹ́ OLÚWA gbogbo orílẹ̀ èdè yóò péjọ sí Jérúsálẹ́mù láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ OLÚWA, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle burúkú wọn mọ́.