Jeremiah 3:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ wọnnì, ile Juda yio rin pẹlu ile Israeli, nwọn o jumọ wá lati ilẹ ariwa, si ilẹ ti emi ti fi fun awọn baba nyin li ogún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Júdà yóò darapọ̀ mọ́ ilé Ísírẹ́lì. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.