Jeremiah 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo gbogbo òkè yíká, ibo ni ẹ kò tíì ṣe àgbèrè dé? Ẹ̀ ń dúró de olólùfẹ́ lẹ́bàá ọ̀nà, bí àwọn obinrin Arabia ninu aṣálẹ̀. Ẹ ti fi ìṣekúṣe yín ba ilẹ̀ náà jẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbe oju rẹ soke si ibi giga wọnnì, ki o si wò, nibo ni a kò ti bà ọ jẹ? Iwọ joko de wọn li oju ọ̀na, bi ara Arabia kan ni iju, iwọ si ti fi agbere ati ìwa buburu rẹ bà ilẹ na jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gbé ojú rẹ sí ibi gíga aláìléso kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò ti fi agbára mú ọ? Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́, o jókòó bí i àwọn alárìnkiri nínú ihà. O ti ba ilẹ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú ìwà panṣágà àti ìwà búburú rẹ.