Jeremiah 3:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga, ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni. Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn; wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A gbọ́ ohùn kan lori ibi giga, ẹkun, ani ẹ̀bẹ awọn ọmọ Israeli pe: nwọn ti bà ọ̀na wọn jẹ, nwọn si ti gbagbe Oluwa, Ọlọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga, ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po, wọ́n sì ti gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run wọn.