Jeremiah 3:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè, ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀; dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lotitọ asan ni eyi ti o ti oke wá, ani ọ̀pọlọpọ oke giga, lõtọ ninu Oluwa Ọlọrun wa ni igbala Israeli wà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrùkèrudò tí ó wà ní àwọn orí òkè kékèké àti àwọn òkè gíga; Nítòótọ́, nínú OLÚWA Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Ísírẹ́lì wà.