Jeremiah 3:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìí ti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run: ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn, àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ohun itiju oriṣa ti jẹ ère iṣẹ awọn baba wa lati igba ewe wa wá, ọwọ́-ẹran wọn ati agbo-ẹran wọn, pẹlu ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti pa èso iṣẹ́ àwọn baba wa, ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.