Jeremiah 3:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá, nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa; àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa, a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa dubulẹ ninu itiju wa, rudurudu wa bò wa mọlẹ, nitoriti awa ti ṣẹ̀ si Oluwa Ọlọrun wa, awa pẹlu awọn baba wa, lati igba ewe wa wá, titi di oni yi, awa kò gba ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa, kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀. A ti ṣẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run wa, àwa àti àwọn baba wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní a kò gbọ́ràn sí OLÚWA Ọlọ́run wa.”