Jeremiah 3:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó mọ̀ pé nítorí ìwà àgbèrè Israẹli, alaiṣootọ, ni mo ṣe lé e jáde, tí mo sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Sibẹsibẹ Juda tí òun pàápàá jẹ́ alaiṣootọ, kò bẹ̀rù, òun náà lọ ṣe àgbèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si wò pe, nitori gbogbo wọnyi ti Israeli apẹhinda ti ṣe agbere, ti mo kọ̀ ọ silẹ ti emi si fun u ni iwe-ikọsilẹ, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò bẹ̀ru, o si nṣe agbere lọ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo fún Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Ṣíbẹ̀ mo rí pé Júdà tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè.