Jeremiah 30:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin eniyan Jakọbu, iranṣẹ mi, ẹ má sì jẹ́ kí àyà fò yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ti òkèèrè wá gbà yín là, N óo gba àwọn ọmọ yín tí wọ́n wà ní ìgbèkùn là pẹlu. Àwọn ọmọ Jakọbu yóo pada ní ìfọ̀kànbalẹ̀ ati ìrọ̀rùn, ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi; ki o má si fòya, iwọ Israeli: nitorina sa wò o, emi o gbà ọ lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati igbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì yio si dẹruba a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì,’ ni OLÚWA wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jínjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jákọ́bù yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì sí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.