Jeremiah 30:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé mo wà pẹlu yín, n óo gbà yín là. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n óo pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo fọn yín ká sí ni n óo parun patapata, ṣugbọn n kò ní pa ẹ̀yin run. N óo jẹ yín níyà, ṣugbọn n kò ní fi ìyà tí kò tọ́ jẹ yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ: bi emi tilẹ ṣe ipari patapata ni gbogbo orilẹ-ède, nibiti emi ti tu ọ ka si, sibẹ emi kì yio ṣe ọ pari patapata: ṣugbọn emi o ba ọ wi ni ìwọn, emi kì o jọ̃ rẹ lọwọ li alaijiya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ ni OLÚWA wí. ‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀ èdè run, nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká, síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátapáta. Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan; Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’