Jeremiah 30:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn olólùfẹ́ yín ti gbàgbé yín; wọn kò bìkítà nípa yín mọ́, nítorí mo ti nà yín bí ọ̀tá mi, mo sì fi ìyà jẹ yín bí ọ̀tá tí kò láàánú, nítorí àṣìṣe yín pọ̀, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn olufẹ rẹ ti gbagbe rẹ; nwọn kò tẹle ọ; nitori ìlù ọta li emi o lù ọ, ni inà alaini ãnu, nitori ọ̀pọlọpọ aiṣedede rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ pọ si i,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ìbátan yín ló ti gbàgbé yín, wọn kò sì náání yín mọ́ pẹ̀lú. Mo ti nà yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀ta yín yóò ti nà yín mo sì bá a yín wí gẹ́gẹ́ bí ìkà nítorí tí ẹ̀bi yín pọ̀ púpọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ yín kò sì lóǹkà.