Jeremiah 30:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ yín run, ni a óo pada jẹ run. Gbogbo àwọn ọ̀tá yín patapata, ni yóo lọ sí ìgbèkùn. Gbogbo àwọn tí wọ́n fogun kó yín ni ogun yóo kó. N óo fi ẹrù àwọn tí wọn ń jà yín lólè fún àwọn akónilẹ́rù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina gbogbo awọn ti o jẹ ọ, li a o jẹ; ati gbogbo awọn ọta rẹ, olukuluku wọn, ni yio lọ si igbekun: ati awọn ti o kó ọ yio di kikó, ati gbogbo awọn ti o fi ọ ṣe ijẹ li emi o fi fun ijẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá, àní gbogbo àwọn ọ̀ta yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjòjì; gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́.