Jeremiah 30:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo fun yín ní ìlera, n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù, Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi o fi ọja imularada lè ọ, emi o si wò ọgbẹ rẹ san, li Oluwa wi; nitori nwọn pè ọ li ẹniti a le jade; Sioni, ti ẹnikan kò ṣafẹri rẹ̀!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín, n ó sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni OLÚWA wí, ‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri Síónì tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’