Jeremiah 30:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Mo ṣetán láti dá ire ilé Jakọbu pada, n óo fi ojurere wo ibùgbé rẹ̀. A óo tún ìlú náà kọ́ sórí òkítì rẹ̀, a óo sì tún kọ́ ààfin rẹ̀ sí ààyè rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o tun mu igbekun agọ Jakobu pada bọ̀; emi o si ṣãnu fun ibugbe rẹ̀; a o si kọ́ ilu na sori okiti rẹ̀, a o si ma gbe ãfin gẹgẹ bi ilana rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “ ‘Èmi yóò dá gbogbo ire àgọ́ Jákọ́bù padà, èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀; ìlú náà yóò sì di títúnṣe tí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀.