Jeremiah 30:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Orin ọpẹ́ yóo máa ti ibẹ̀ jáde wá, a óo sì máa gbọ́ ohùn àwọn tí ń ṣe àríyá pẹlu. N óo bukun wọn, wọn óo di pupọ, n óo sọ wọ́n di ẹni iyì, wọn kò sì ní jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lati inu wọn ni ọpẹ́ ati ohùn awọn ti nyọ̀ yio ti jade: emi o si mu wọn bi si i, nwọn kì o si jẹ diẹ; emi o ṣe wọn li ogo pẹlu, nwọn kì o si kere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti ìyìn yóò sì ti máa jáde. Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀, wọn kì yóò sì dínkù ní iye, Èmi yóò fi ọlá fún wọn, wọn kò sì ní di ẹni àbùkù.