Jeremiah 30:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ wọn yóo rí bí wọn ti rí ní àtijọ́, àwọn ìjọ wọn yóo fi ìdí múlẹ̀ níwájú mi. N óo sì fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn ń ni wọ́n lára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ wọn pẹlu yio ri bi ti iṣaju, ijọ wọn li a o fi idi rẹ̀ mulẹ niwaju mi, emi o si jẹ gbogbo awọn ti o ni wọn lara niya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí. Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára, ni èmi yóò fìyà jẹ.