Jeremiah 30:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn, ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn; n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi, nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọla rẹ̀ yio si jẹ lati inu ara wọn wá, alakoso rẹ̀ lati ãrin rẹ̀; emi o si mu u sunmọ tosi, on o si sunmọ ọdọ mi: nitori tani ẹniti o mura ọkàn rẹ̀ lati sunmọ ọdọ mi? li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn, Ọba wọn yóò dìde láti àárin wọn. Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi, nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jìn láti súnmọ́ mi?