Jeremiah 30:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí pé àkókò ń bọ̀ tí n óo dá ire àwọn eniyan mi, Israẹli ati Juda pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo mú wọn pada wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì di ohun ìní wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu igbekun awọn enia mi, Israeli ati Juda, pada, li Oluwa wi: emi o si mu ki nwọn pada bọ̀ si ilẹ ti emi fi fun awọn baba wọn, nwọn o si ni i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni OLÚWA Ọlọ́run wí.”