Jeremiah 30:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ bèèrè, kí ẹ sì ṣe ìwádìí; ǹjẹ́ ọkunrin lè lóyún kí ó sì bímọ? Kí ló wá dé tí mo rí gbogbo ọkunrin, tí wọn ń dáwọ́ tẹ ìbàdí bí obinrin tí ń rọbí? Kí ló dé tí gbogbo yín fajúro?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin sa bere, ki ẹ si ri bi ọkunrin a mã rọbi ọmọ: Ẽṣe ti emi fi ri gbogbo awọn ọkunrin pẹlu ọwọ wọn li ẹgbẹ wọn, bi obinrin ti nrọbi, ti a si sọ gbogbo oju di jijoro?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Béèrè kí o sì rí: Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí? Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọn sì fàro fún ìrora?