Jeremiah 30:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá, n óo já àjàgà kúrò lọ́rùn wọn. N óo já ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi so wọ́n, wọn kò sì ní ṣe iranṣẹ fún àjèjì mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi o si ṣẹ àjaga kuro li ọrùn rẹ, emi o si ja ìde rẹ, awọn alejo kì yio si mu ọ sìn wọn mọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ OLÚWA wí pé; ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn alejo kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́