Jeremiah 31:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré; ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ, yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède, ẹ sọ ọ ninu erekuṣu òkere, ki ẹ si wipe, Ẹniti o tú Israeli ka yio kó o jọ, yio si pa a mọ, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo-ẹran rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin orílẹ̀ èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùsù jínjìn; ‘Ẹni tí ó bá tú Ísírẹ́lì ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn.’