Jeremiah 31:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà, àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá. N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn wúndíá yóò jó, wọn ó sì kún fún ayọ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọkùnrin àti obìnrin. Èmi yóò sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀, dípò ìkorò èmi yóò tù wọ́n nínú. Èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀.