Jeremiah 31:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni. Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “A gbọ́ ohùn kan ní Rámà tí ń sọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò. Rákélì ń sọkún fún àwọn ọmọ rẹ̀; kò gbà kí wọ́n tu òun nínú, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.”