Jeremiah 31:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni? Ṣé ọmọ mi àtàtà ni? Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀, nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí; dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ ọ̀wọn ha ni Efraimu fun mi bi? ọmọ inu-didùn ha ni? nitori bi emi ti sọ̀rọ si i to, sibẹ emi ranti rẹ̀, nitorina ni ọkàn mi ṣe lù fun u; emi o ṣe iyọ́nu fun u nitõtọ, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Éfúráímù kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára tí inú mi dùn sí bí? Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó, síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀. Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un, èmi káàánú gidigidi fún un,” ni OLÚWA wí.