Jeremiah 31:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóo tún máa lo gbolohun yìí ní ilẹ̀ Juda ati ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, wọn óo máa wí pé, ‘OLUWA yóo bukun ọ, ìwọ òkè mímọ́ Jerusalẹmu, ibùgbé olódodo.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Nwọn o si tun lò ède yi ni ilẹ Juda ati ni ilu rẹ̀ wọnni, nigbati emi o mu igbekun wọn pada, pe, Ki Oluwa ki o bukun ọ, Ibugbe ododo, Oke ìwa-mimọ́!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan síi; wí pé, ‘OLÚWA bùkún fún ọ, ìwọ tí ń gbé nínú òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’